- Fi àáké kọ́rí
Meaning: to refuse completely.
Example: a bèbè títí sùgbọ́n ó fi àáké kori pé Òun ò ní gbà
2. Àárọ̀ ọjọ́
Meaning: childhood or youthful
Example: Ọmọ náà ní ìwà akíkanjú ní àárọ̀ ọjọ́ rẹ̀
3. Fi àbàrá kékeré gba ńlá
Meaning: to receive a heavy blow in return for a light one inflicted on someone else
Example: wàá fi àbàrá Kékeré gba ńlá tí o bá gbéjẹ́
4. Kan ojú abẹ ní ìkó
Meaning: to go straight to the point.
Example: kò fi àkókò wa sòfò, ó kan ojú abẹ ní ìkó
5. Abùṣe bùṣe
Meaning: the matter is ended
Example: bí a bá ti bẹ̀bẹ̀, abùṣe bùṣe
6. Àfi orí afi ọrùn
Meaning: at all cost
ofẹ́ ó kọ̀, Wàá délé; àfi orí afi ọrùn.
7. Ṣe àfọwọ́ra
Meaning: to steal petty things
Ẹ máa bójútó ọmọ yín, ó nse àfọwọ́ra
8. Fi aga gbága
Meaning: to compete.
Example: Táiyé ńfi aga gbára pèlu ọ̀rẹ́ rẹ̀
9. Dá nÍ agara
Meaning: to push someone to the wall or to become disgusted
Example: àtẹnumọ́ kìí pẹ́ dá mi l’ágara
10. Ko àgbákò
Meaning: to be unfortunate
11. Já sí agbami
Meaning: to let someone down / to be disappointed
Example: obìnrin yẹn já a sí agbami
12. Àgbọ́ fọwọ́ dití
Meaning: meaningless talk or a loud noise
Example: ọ̀rọ̀ àgbọ́ dití lásán lóun sọ
13. Jálé agbọ́n
Meaning: to cause oneself a misfortune.
Example: ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ jálé agbọ́n nígbà tó gba ìyàwó ọ̀rẹ́ rẹ̀
14. Ké àgò
Meaning: ask for permission
Example: mo k’ágò fó n’ílé o.
15. Ti ajá ti ẹran
Meaning: all sorts of
Example: t’ajá t’ẹran ló wá sí ìpàgọ́ àná
16. Akéré korò
Meaning: a short devil
Ènìyàn kúkúrú bìlísì, akéré korò ẹ̀dá
17. Alárìnjẹ
Meaning: a vagabond
Example: alárìnjẹ ni okùnrin náà
18. Tẹ ojú ajẹ́ mọ́lẹ̀
Meaning: to be extravagant
19. Lái sí àníyàn
Meaning: with no hesitation
Example: mo máa lọ sí èkó, lái sí àníyàn
20. Da àníyàn sí ọ̀nà kan soso
Meaning: put all eggs in one basket
Example: kò dára láti da àníyàn sí ọ̀nà kan soso
21. Anù mọ́ dàárò
Meaning: an aimless wanderer
Example: ọmọlúàbí kìí wùwà anù mọ́ dàárò
22. Fi ara balẹ̀
Meaning: to be patient and at alert
Example: fi ara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ
23. Fi ara dàá
Meaning: endure
Example: ọmọ tí ó bá f’ara da ẹ̀gbin iṣẹ́ kíkọ́ ni yóò k’érè rẹ̀
24. Ara fífà
Meaning: indisposition
Example: mo lọ rèé rí onísègùn nítorí ara mi fà díẹ̀
25. Fi ara hàn
Meaning: to present oneself
Example: mo fi ara hàn ní ilé ẹjọ́
26. Ará rọ̀ọ́
Meaning: to be comfortable or relieved
Example: ará rọ̀ mí nígbàtí mo bẹ̀erẹ̀ isẹ́ titun
27. Fi ara sílẹ̀
Meaning: to be caught unawares, unalert, not cautious
Example: nígbà tí ó fi ara sílẹ̀ ni ọwọ́ bàá
28. Fi ara sinko
Meaning: hide
Example: olóyè máa nf’ara sinko nígbàtí ó bá lọ sí ìlú tí ati bíi
29. Gbé ara sọ
Meaning: to stretch oneself beyond assumed capability
Example: àbúrò mi gbéra sọ nígbàtí ódé ọ̀dọ̀ ògáa rẹ̀
30. Fi ara wé
Meaning: to imitate or copy
Example: okùnrin yẹn nfi ara wé mi
31. Àṣírí tú
Meaning: a secret is exposed
Example: àṣírí olùkọ́ ti tú sí ọwọ́ ọmọ ilé ìwé
32. Tẹ orí gba aṣọ
Meaning: to die
Example: mo gbọ́ pé ọ̀tá mi ti tẹ orí gbasọ
33. Pa àtẹ́
Meaning: (derogatory) to display a behaviour
Example: aláì lójútì, ó tún ti pàtẹ ìbàjẹ́ rẹ̀.
34. Awọ ò kájú ìlù
Meaning: Lack or inability to make ends meet
Example: mo fẹ́ sapá, àmọ́, awọ ò kájú ìlù
35. Dé ara mọ́ awo olóókan
Meaning: to know one’s limit
Example: tí o ba dé ara rẹ mọ́ awo olóókan, oò ní di ẹlẹ́tẹ̀ẹ́
36. Awó ya
Meaning: the secret is unveiled
Example: kò sí ọ̀rẹ́ mó, awó ti ya
37. Ní àyà
Meaning: to be brave and courageous
Example: ọmọdé yìí ní àyà ju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀
38. Fi àyà tìí
Meaning: to endure/ stand with
Example: ìyàwó náà fi àyà ti ìsòro ilé ọkọ
39. Ṣe àyà gbàagbà
Meaning: to be bold and fearless
Example: ọmọ orí ìrìn ni, ó se àyà gbàa gbà
40. Ayírí
Meaning: unstable / unreliable person
Example: ayírí ni ọ̀rẹ́ mi, bópé òun áwá, ó le má wàá
41. Bá ẹkùn ní bùba
Meaning: to encounter danger unexpectedly
Example: bí ó se wọlé lái lerò, ó bá ẹkùn ní bùba, àjèjì olóngbò ló rí
42. Bá lójijì
Meaning: shocked/surprised
Ọ̀rọ̀ náà bá mi lójiiji.
43. Ba ojú jẹ́
Meaning: to express displeasure
Example: ó bojú jẹ́ nítorí mo ní kómá lo seré
44. Baba ní igbẹ́jọ́
Meaning: godfather or support
Example: ọkàn rẹ̀ balẹ̀ nítorí ó ní baba nígbẹ́jọ́
45. Bàsèjẹ́
Meaning: destroyer
Example: kòda láti dòwò pọ̀ pèlu bàṣèjẹ́
46. Bẹ́ ejò lórí
Meaning: to provide an immediate solution to a problem
Example: bí wọ́n ti gbé ọ̀rọ̀ dé ọ̀dọ bàbá, kíá ni ó bẹ́ ejò lórí
47. Bẹ ilẹ̀ wò
Meaning: to get information in a cunny way
Example: ó bẹ ilẹ̀ wò títí ó fi mọ òdodo ọ̀rọ̀
48. Bojú bojú
Meaning: secrecy
Example: bojú bojú ni ọjà ti ́ó ntà
49. Bònkẹ́lẹ́
Meaning: secret
Example: ìgbéyàwó oní bònkẹ́lẹ́ ni wọ́n se.
50. Bọ́ lọ́wọ́
Meaning: to escape or to lose something
Example: isẹ́ ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀
We referenced the works of Chief M.A Fabunmi and Professor Wande Abimbola on Yoruba Idioms.
To support our research, you can make payment via the secured paystack by clicking here.