1a. Àbíjọ ni a nmọ ìtan
1b. Physical resemblance reveals relatives
2a. Àbí ìkọ́, àkọ́ ìgbọ́, òde ni wọ́n tií nkọ́ ọgbọ́n wálé
2b. Untrained children will be corrected outside. This proverb is used especially for people that are unruly and unnecessarily impossible.
3a. Àbíkú sọ ológùn dèké
3b. Still birth turns the doctor a liar. An expression used when there is a failed attempt in an endeavour.
4a. A bímọ kò gbọ́n, a ní kí ó sa má kùú, kílí ó npa ènìà bi àìgbọ́n
4b. Not improving a child’s intellect is exposing the child to danger. Also solve the root cause of a problem. Otherwise, expect the worst.
5a. Abínú ẹni kò lè pa kádàrá dà
5b. Hatred cannot alter one’s destiny.
6a. Abiyamọ ọ̀tá àgàn, ẹni nṣiṣé ọ̀tá ọ̀lẹ
6b. A barren woman is jealous of a mother, a lazy man is jealous of the one that works. People are always jealous of others that are better than them.
7a. Àdàbà kò náání à ńkún gbẹ́, iná jo ẹiyẹ fò lọ
7b. Fire does not distress a dove, once it sees the flame, it flies away.
8a. Àdàbà ńfògèdè, o ṣebí ẹiyẹlé kò gbọ́, ẹiyẹlé gbọ́, títiri l’ó ńtiri
8b. The dove says incarntation but the pigeon pretends not to hear. it is sometimes wise to ignore certain situations.
9a. Adájàsílẹ̀ takété
9b. One who initiates quarrel and stand aloof. This is used to describe the devil’s advocate in a misunderstanding or confusing situation.
10a. Adánilóró f’agbára kọ́ni
10b. The tormentor makes his victim stronger.
11a. Adánitán ti dá ni tán kí abanijẹ́ tó dé, nígbàtí abanijẹ́ sì dé, ó bá ni lọ́wọ́ atúnniṣe
11b. The creator had completed his work before the destroyer came, when the destroyer came, he met us with the redeemer. There’s always a way out of the enemies’ trap.
12a. Àdán doríkodò o nwo ìṣe ẹiyẹ
12b. Still water runs deep ( the bat heads down to observe the bird).
13a. Àdánul ńláńlá ni fún ẹni tí ó fẹ ni tí a kò fẹ́
13b. Unrequited love is a great loss
14a. Àdáse nií wun ni, àjọse kìi wun ni
14b. One man is not responsible for the consequence of a joint effort and vice versa.
15a. Adìẹ bà lé okùn, ara kò rọ okùn, ara kò rọ adìẹ
15b. A chicken perches on a rope, both the rope and chicken feel uneasy. When you disturb people, you are indirectly disturbing yourself.